19. Nígbà tí Jòhánù sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Jésù, wí pé, “Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”
20. Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Jòhánù Onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, ‘Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’ ”
21. Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti àrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú.
22. Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yín rí, tí ẹ̀yín sì gbọ́ fún Jòhánù: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúkún-ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòsì ni à ń wàásù ìyìn rere.
23. Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”
24. Nígbà tí àwọn oníṣẹ Jòhánù padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ síí sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Jòhánù pé, “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò? Iféfèé tí afẹ́fẹ́ ń mì?
25. Ṣùgbọ́n kínni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba!
26. Ṣùgbọ́n kíni ẹ̀yin jáde lọ wò? Wòlíì? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ!
27. Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé:“ ‘Wò ó, mo rán oníṣẹ́ mi ṣíwájú rẹ;ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’
28. Mo wí fún yín nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí wòlíì tí ó pọju Jòhánù Onítẹ̀bọmi lọ: ṣùgbọ́n ẹni tí ó kéré jùlọ ní ìjọba Ọlọ́run, ó pọ̀ jù ú lọ.”
29. (Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Jòhánù tẹ̀ wọn bọ mi.