20. Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélèbú.
21. Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Ísírẹ́lì ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹ́ta tí nǹkan wọ̀nyí ti sẹlẹ̀.
22. Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá dá wa níjì:
23. Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn ańgẹ́lì tí wọ́n wí pé, ó wà láàyè.
24. Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí: ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ ni wọn kò rí.”
25. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́:
26. Kò ha yẹ kí Kírísítì ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.”
27. Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mósè àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.
28. Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ: ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú.
29. Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró.
30. Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fifún wọn.
31. Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú
32. Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”
33. Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn,
34. Èmí wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Símónì!”