Lúùkù 22:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbérò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́.

5. Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mu láti fún un ní owó.

6. Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.

7. Ojọ́ àkàrà àìwú pé, nígbà tí wọ́n ní láti ṣe ìrúbọ ìrékọjá.

8. Ó sì rán Pétérù àti Jòhánù, wí pé, “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ”

9. Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?”

Lúùkù 22