Lúùkù 20:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ijọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹ́ḿpìlì tí ó sì ń wàásù ìyìn rere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn alàgbà dìde sí i.

2. Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe ǹkan wọ̀nyí? Tàbí tani ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”

3. Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi.

4. Bamitísímù ti Jòhánù, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”

5. Wọ́n sì bá ara wọn gbérò pé, “Bí àwa bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun ó wí pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’

6. Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Jòhánù.”

7. Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Wọn kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.”

8. Jésù sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”

9. Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùsọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́.

10. Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùsọ́gbà náà: kí wọn lè fún un nínú èṣo ọgbà àjàrà náà: ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.

11. Ó sì tún rán ọmọ-ọ̀dọ̀ míràn: wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ níyà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.

12. Ó sì tún rán ẹ̀kẹ́ta: wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.

13. “Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn ó ṣojúsájú fún un.’

Lúùkù 20