Lúùkù 18:36-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó bèèrè pé, kíni a lè mọ èyí sí.

37. Wọ́n sì wí fún un pé, “Jésù ti Násárẹ́tì ni ó ń kọjá lọ.”

38. Ó sì kígbe pé, “Jésù, ìwọ ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi!”

39. Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi!”

40. Jésù sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í,

41. Wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?”Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”

Lúùkù 18