Lúùkù 18:20-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ìwọ mọ̀ àwọn òfin, ‘Má ṣe ṣe panṣágà, má ṣe pànìyàn, má ṣe jalè, má ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá rẹ.’ ”

21. Ó sì wí pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pa mọ́ láti ìgbà èwe mi wá.”

22. Nígbà tí Jésù sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn talákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra lọ́run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

23. Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi: nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

24. Nígbà tí Jésù rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, ó wí pé, “Yóò ti ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!

25. Nítorí ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run lọ.”

26. Àwọn tí ó sì gbọ́ wí pé, “Ǹjẹ́ tani ó ha lè là?”

27. Ó sì wí pé, “Ohun tí ó ṣòro lọ́dọ̀ ènìyàn kò ṣòro lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”

28. Pétérù sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa silẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!”

29. Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run,

30. Tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”

31. Nígbà náà ni ó pe àwọn méjìlá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Sá wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerúsálémù, a ó sì mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, nítorí Ọmọ Ènìyàn.

32. Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ si i lára.

Lúùkù 18