4. Bí ó bá sì sẹ̀ ọ́ ní ẹ̀rìnméje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ẹ̀rẹ̀méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dárí jìn ín.”
5. Àwọn àpósítélì sì wí fún Olúwa pé, “Bùsí ìgbàgbọ́ wa.”
6. Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn músítadì, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi Músítádì yìí pé, ‘Kí a fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú òkun,’ yóò sì gbọ́ ti yín.
7. “Ṣùgbọ́n tani nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójú kan náà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Lọ í jòkòó láti jẹun’?
8. Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, ‘Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán; lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu’?
9. Òun ó ha máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pa láṣẹ fún un bí? Èmi kò rò bẹ́ẹ̀.