Lúùkù 14:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ó wọ ilé ọ̀kan nínú àwọn olórí Farisí lọ ní ọjọ́ ìsinmi láti jẹun, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ.

2. Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí ó ní àsunkún ń bẹ níwájú rẹ̀.

3. Jésù sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisí pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti múni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbi kò tọ́?”

4. Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó sì mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ.

Lúùkù 14