Léfítíkù 3:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.

12. “ ‘Bí ó bá ṣe pé ewúrẹ́ ni ó mú, kí ó mú un wá ṣíwájú Olúwa.

13. Kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí. Kí ó sì pa á ní iwájú àgọ́ ìpàdé. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Árónì yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.

14. Lára ọrẹ tó mú wá, kí ó mú ọrẹ sísun fún Olúwa, gbogbo ọ̀rá tó bo nǹkan inú rẹ̀ àti ohun gbogbo tó so mọ́ ọn.

Léfítíkù 3