21. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹran ọ̀sìn gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ni kí ẹ pa.
22. Òfin kan náà ló wà fún àlejò àti fún ọmọ Ísírẹ́lì. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”
23. Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì mú asọ̀rọ̀òdì náà lọ sí ẹ̀yìn àgọ́: wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mósè.