Léfítíkù 23:5-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Àjọ ìrékọjá Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní (Épírì).

6. Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kìnm-ín-ní ni àjọ̀dún àkàrà àìwú (àkàrà tí kò ní ìwúkàrà) tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.

7. Ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́ yín.

8. Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa. Ní ọjọ́ keje, ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́.’ ”

9. Olúwa sọ fún Mósè pe

10. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fún yín, tí ẹ bá ń ṣe ìkórè, kí ẹ mú síírì ọkà àkọ́kọ́ tí ẹ kórè wá fún àlùfáà.

11. Kí o fí síírì ọkà náà níwájú Olúwa, kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín: kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi.

12. Ní ọjọ́ tí ẹ bá fí síírì ọkà náà, kí ẹ mú ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dúnkan láìní àbùkù rú ẹbọ sísun sí Olúwa.

13. Pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ tí ó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ẹ́fà (èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi òróró pò ọrẹ tí a fi iná ṣe fún Olúwa òórùn dídùn pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀ tí í ṣe ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hini (Èyí jẹ́ lítà kan).

14. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.

15. “ ‘Ẹ ka ọ̀sẹ̀ méje gbangba, láti ọjọ́ kejì ọjọ́ ìsinmi, àní ọjọ́ tí ẹ mú sììrì ọkà fífì wá.

16. Ẹ ka àádọ́ta (50) ọjọ́ títí dé ọjọ́ kejì ọ̀sẹ̀ méjèèje, kí ẹ sì mú ọrẹ ọkà titun wá fún Olúwa.

17. Láti ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, ẹ mú ìṣù àkàrà méjì tí a fi òṣùwọ̀n ìdáméjì nínú mẹ́wàá tí ẹ́fà (Èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi ìwúkàrà ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì àkọ́so sí Olúwa.

18. Ẹ fi akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù, ọmọ màlúù kan àti àgbò méjì kún àkàrà yìí: wọn yóò jẹ́ ọrẹ sísun sí Olúwa.

19. Lẹ́yìn náà kí ẹ fi akọ ewúrẹ́ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọ̀dọ́ àgùntàn méjì ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan fún ọrẹ àlàáfíà.

20. Kí àlùfáà fí ọ̀dọ́ àgùntàn méjèèjì náà níwájú Olúwa bí i ọrẹ fífì pẹ̀lú oúnjẹ àkọ́so wọn jẹ́ ọrẹ mímọ́ sí Olúwa fún àlùfáà.

21. Ní ọjọ́ yìí náà ni kí ẹ kéde ìpàdé àjọ mímọ́: ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́ Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀ níbi yòówù tí ẹ ń gbé.

22. “ ‘Nígbà tí ẹ bá kórè ilẹ̀ yín ẹ má ṣe kórè dé ìkangun oko yín, tàbí kí ẹ padà gé èyí tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ nínú ìkórè yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tálákà àti àwọn àlejò: Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

Léfítíkù 23