38. Àwọn ọrẹ wọ̀nyí wà ní àfikún pẹ̀lú àwọn ọrẹ ọjọ́ ìsinmi Olúwa, àti pẹ̀lú ẹ̀bùn yín àti ohunkóhun tí ẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ àti gbogbo ọrẹ àtinúwá yín fún Olúwa.)
39. “ ‘Torí náà, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹẹ̀dógún osù kéje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti kórè ilẹ̀ náà, ẹ se àjọ̀dún yìí fún Olúwa ní ọjọ́ méje. Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹjọ pẹ̀lú si tún jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.
40. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí ẹ mú àṣàyàn èso láti orí igi, igi tẹ́ẹ́rẹ́ etídò, àti ẹ̀ka igi tó rúwé, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.
41. Ẹ ṣe èyí ní àjọ̀dún sí Olúwa fún ọjọ́ méje lọ́dọọdún. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀: Ẹ ṣe é ní oṣù keje.
42. Ẹ gbé inú àgọ́ fún ọjọ́ méje. Kí gbogbo ọmọbíbí Ísírẹ́lì gbé nínú àgọ́.