27. “Nígbà tí màlúù bá bímọ, tí àgùntàn bímọ, tí ewúrẹ́ sì bímọ, ọmọ náà gbọdọ̀ wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Láti ọjọ́ kèjọ ni ó ti di ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ àfinásun sí Olúwa.
28. Ẹ má ṣe pa màlúù àti ọmọ rẹ̀ tàbí àgùntàn àti ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.
29. “Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ ọpẹ́ sí Olúwa, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóò fí jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín.
30. Ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà gan an: Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀. Èmi ni Olúwa.
31. “Ẹ pa òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.