21. Bí ẹnikẹ́ni bá mú ọrẹ àlàáfíà wá láti inú agbo màlúù tàbí ti àgùntàn, fún Olúwa láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí fún ọrẹ àtinúwá. Ó gbọdọ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láìní àbùkù.
22. Ẹ má ṣe fi ẹranko tí ó fọ́jú, tí ó farapa, tí ó yarọ, tí ó ní koko, tí ó ní èkúkú, èépá àti egbò kíkẹ̀ rúbọ sí Olúwa. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé èyíkeyi nínú wọn sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bi ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.
23. Ẹ le mú màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù tàbí tí ó yọ iké wá fún ọrẹ àtinúwá ṣùgbọ́n kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ ẹ̀jẹ́.
24. Ẹ má ṣe fi ẹranko tí kóró ẹpọ̀n rẹ̀ fọ́ tàbí tí a tẹ̀, tàbí tí a yà tàbí tí a là rúbọ sí Olúwa. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí ní ilẹ̀ yín.
25. Ẹ kò gbọdọ̀ gba irú ẹranko bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò kankan láti fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ sí Ọlọ́run yín. A kò ní gbà wọ́n fún yín nítorí pé wọ́n ní àbùkù wọ́n sì díbàjẹ́.’ ”