Léfítíkù 22:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ẹ má ṣe mú ohunkóhun tí ó ní àbùkù wá, torí pé kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín.

21. Bí ẹnikẹ́ni bá mú ọrẹ àlàáfíà wá láti inú agbo màlúù tàbí ti àgùntàn, fún Olúwa láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí fún ọrẹ àtinúwá. Ó gbọdọ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láìní àbùkù.

22. Ẹ má ṣe fi ẹranko tí ó fọ́jú, tí ó farapa, tí ó yarọ, tí ó ní koko, tí ó ní èkúkú, èépá àti egbò kíkẹ̀ rúbọ sí Olúwa. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé èyíkeyi nínú wọn sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bi ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.

Léfítíkù 22