1. “ ‘Bí ẹnìkan bá mú ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ wá fún Olúwa ọrẹ rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun darádara, kí ó da òróró sí i, kí o sì fi tùràrí sí i,
2. kí ó sì gbé lọ fún àwọn ọmọ Árónì tí í se àlùfáà. Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ìyẹ̀fun àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí kí ó sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ọrẹ tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
3. Ìyòókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ náà jẹ́ ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ ìpín tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.