Léfítíkù 18:6-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. “ ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀, èmí ni Olúwa.

7. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀.

8. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyàwó bàbá rẹ lòpọ̀: nítorí ìhòòhò bàbá rẹ ni.

9. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin rẹ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lòpọ̀, yálà a bí i nílé yín tàbí lóde.

10. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin, ọmọ rẹ ọkùnrin lòpọ̀ tàbí ọmọbìnrin ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀ nítorí pé ìhòòhò wọn, ìhòòhò ìwọ fúnrarẹ ni.

11. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin aya bàbá rẹ lòpọ̀; èyí tí a bí fún bàbá rẹ nítorí pé arábìnrin rẹ ni

12. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin bàbá rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan bàbá rẹ ni.

13. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin mọ̀mọ́ rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan ìyá rẹ ni.

14. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u arákùnrin bàbá rẹ: nípa sísun mọ́ aya rẹ̀ láti bá a lòpọ̀ nítorí pé ìyàwó ẹ̀gbọ́n bàbá rẹ ni.

15. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọ àna obìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé aya ọmọ rẹ ni. Má ṣe bá a lòpọ̀.

16. “ ‘Má ṣe bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ ọkùnrin lòpọ̀ nítorí pé yóò tàbùkù ẹ̀gbọ́n rẹ.

17. “ ‘Má ṣe bá ìyá àti ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin ọmọbìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan rẹ tímọ́tímọ́ ni: nítorí àbùkù ni.

18. “ ‘Má ṣe fẹ́ àbúrò ìyàwó rẹ obìnrin ní aya gẹ́gẹ́ bí orogún tàbi bá a lòpọ̀, nígbà tí ìyàwó rẹ sì wà láàyè.

19. “ ‘Má ṣe súnmọ́ obìnrin láti bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù, nítorí àkókò àìmọ́ ni.

20. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá aya aládúgbò rẹ lòpọ̀, kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.

21. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ rúbọ lórí pẹpẹ sí òrìṣà Mólékì, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.

22. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọkùnrin lòpọ̀ bí ìgbà tí ènìyàn ń bá obìnrin lòpọ̀: ìríra ni èyí jẹ́.

23. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀ kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́. Obìnrin kò sì gbọdọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀, ohun tó lòdì ni.

Léfítíkù 18