Léfítíkù 18:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ẹ pa àṣẹ àti òfin mi mọ́. Ẹni tí ó bá ṣe ìgbọ́ràn sí wọn yóò máa gbé nípa wọn, Èmi ni Olúwa.

6. “ ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀, èmí ni Olúwa.

7. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀.

8. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù u bàbá rẹ nípa bíbá ìyàwó bàbá rẹ lòpọ̀: nítorí ìhòòhò bàbá rẹ ni.

9. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin rẹ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lòpọ̀, yálà a bí i nílé yín tàbí lóde.

Léfítíkù 18