3. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ènìyàn Gíbíónì gbọ́ ohun tí Jóṣúà ṣe sí Jẹ́ríkò àti Áì,
4. wọ́n dá ọgbọ́n ẹ̀tàn. Wọ́n lọ bí aṣojú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn: tí kún fún àwọn àpò tó ti gbó, àti àwọn awọ ọtí wáìnì tó ti gbó tí a tún rán.
5. Àwọn ọkùnrin náà sì wọ bàtà àti aṣọ tí ó ti gbó. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n pèsè fún ara wọn sì bu.
6. Wọ́n sì tọ Jóṣúà lọ ní ibùdó ní Gílígálì, wọ́n sì sọ fún òun àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé, “Ìlú òkèrè ní àwọn ti wá, ẹ ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wa.”
7. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fún àwọn ará Hífì pé, “Ṣùgbọ́n bóyá tòsí wa ni ẹ ń gbé. Báwo ni a ó ṣe lè se àdéhùn pẹ̀lú yín?”