1. Nígbà tí gbogbo àwọn ọba Ámórì ti ìlà-oòrùn Jọ́dánì àti gbogbo àwọn ọba Kénánì tí ń bẹ létí òkun gbọ́ bí Olúwa ti mú Jọ́dánì gbẹ ní iwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí ti a fi kọjá, ọkàn wọn pámi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ìgboyà mọ́ láti dojú kọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
2. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Jóṣúà pé, “Fi akọ òkúta ṣe abẹ kí o sì kọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilà ní ìgbà ẹ̀ẹ̀kéjì.”
3. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà sì ṣe abẹ akọ òkúta, ó sì kọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilà, ní Gíbíátì-Hárálótù.
4. Wàyí o, ìdí tí Jóṣúà fi kọ wọ́n nílà nìyìí: Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó ti Éjíbítì jáde wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun kú ní asálẹ̀ ní ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.
5. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo àwọn ọkùnrin tó jáde láti Éjíbítì ni a ti kọ ní ilà, síbẹ̀ gbogbo ènìyàn tí a bí nínú asálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní Éjíbítì ni wọn kò kọ ní ilà.
6. Àwọn ará Ísírẹ́lì rìn ní ihà fún ogójì (40) ọdún títí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó tó ogun n jà nígbà tí wọ́n kúrò ni Éjíbítì fi kú, nítorí wọn kò gbọ́ràn sí Olúwa. Nítorí Olúwa ti búra fún wọn pé wọn kò ní rí ilẹ̀ tí òun ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn láti fí fun wa, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.