Jóṣúà 4:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ní ọjọ́ kẹwàá (10) osù kìn-ní-ní (1) àwọn ènìyàn náà lọ láti Jọ́dánì, wọ́n sì dúró ní Gílígálì ní ìlà-oòrùn Jẹ́ríkò.

20. Jóṣúà sì to àwọn òkúta méjìlá (12) tí wọ́n mú jáde ní Jọ́dánì jọ ní Gílígálì.

21. Ó sì sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí yìí dúró fún?’

22. Nígbà náà ni ẹ ó jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé, ‘Ísírẹ́lì rékọjá odò Jọ́dánì ní orí ilẹ̀ gbígbẹ.’

Jóṣúà 4