Jóṣúà 23:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ẹ má ṣe ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tí ó sẹ́kù láàárin yín; ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà wọn tàbí kí ẹ fi wọ́n búra. Ẹ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tàbí ki ẹ tẹríba fún wọn.

8. Ṣùgbọ́n ẹ di Olúwa Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń se tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí.

9. “Olúwa ti lé àwọn orílẹ̀ èdè ńlá àti alágbára kúrò níwájú yín; títí di òní yìí kò sí ẹnìkan tí ó le dojú kọ yín.

Jóṣúà 23