3. Ẹ̀yin tìkára yín sì ti rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀nyí nítorí yín, Olúwa Ọlọ́run yín ni ó jà fún yín.
4. Ẹ rántí bí mo ṣe pín ogún ìní fún àwọn ẹ̀yà yín ní ilẹ̀ orílẹ̀ èdè gbogbo tí ó kù; àwọn orílẹ̀ èdè tí mo ti sẹ́gun-ní àárin Jọ́dánì àti Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.
5. Olúwa Ọlọ́run yín fúnra rẹ̀ yóò lé wọn jáde kúrò ní ọ̀nà yín, yóò sì tì wọ́n jáde ní iwájú yín, ẹ̀yin yóò sì gba ilẹ̀-ìní wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún yín.
6. “Ẹ jẹ́ alágbára gidigidi, kí ẹ sì sọ́ra láti ṣe ìgbọ́ran sí ohun tí a kọ sí inú Ìwé Ofin Mósè, láìyí padà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.
7. Ẹ má ṣe ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tí ó sẹ́kù láàárin yín; ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà wọn tàbí kí ẹ fi wọ́n búra. Ẹ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tàbí ki ẹ tẹríba fún wọn.
8. Ṣùgbọ́n ẹ di Olúwa Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń se tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí.
9. “Olúwa ti lé àwọn orílẹ̀ èdè ńlá àti alágbára kúrò níwájú yín; títí di òní yìí kò sí ẹnìkan tí ó le dojú kọ yín.