Jóṣúà 21:42-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìlú wọ̀nyí ni ó ni ilẹ̀ pápá oko tí ó yí ì ká, bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún gbogbo ìlú wọ̀nyí.

43. Báyìí ni Olúwa fún Ísírẹ́lì ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí láti fi àwọn fún baba ńlá wọn. Nígbà tí wọ́n sì gbà á tan wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀.

44. Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí ó ti sèlèrí fún baba ńlá wọn. Kò sì sí ọ̀kankan nínú àwọn ọ̀ta wọn tí ó lè dojú kọ wọ́n. Olúwa sì fi gbogbo àwọn ọ̀ta wọn lé wọn ní ọwọ́.

45. Kò sí ọ̀kan nínú ìlérí rere tí ó se fún ilé Ísírẹ́lì tí ó kùnà. Gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe.

Jóṣúà 21