Jóṣúà 20:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Bí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ bá ń lépa wọn, wọn kò gbọdọ̀ fi àwọn ọ̀daràn náà lé wọn lọ́wọ́, nítorí.

6. Òun ó sì máa gbé inú ìlú náà, títí yóò fi jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn àti títí ikú olórí àlùfáà tí ó ń siṣẹ́ ìsìn nígbà náà. Nígbà náà ó lè padà sí ilé rẹ̀ ní ìlú tí ó ti sá wá.”

7. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan Kedésì ní Gálílì ní ìlú òkè Náfítanì, Sékémù ní ìlú òkè Éfúráímù, àti Kíríátì aginjù (tí í ṣe, Hébúrónì) ní ìlú òkè Júdà.

8. Ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì ti Jẹ́ríkò, wọ́n ya Bésẹ́rìù ní aṣalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Rámótì ní Gílíádì ní ẹ̀yà Gádì, àti Golanì ní Básánì ní ẹ̀yà Mánásè.

9. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàbí àlejò tí ń gbé ní àárin wọn tí ó sèèsì pa ẹnìkan lè sálọ sí àwọn ìlú tí a yà sọ́tọ̀ wọ̀nyí, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má sì ṣe pa á kí ó to di àkókò tí yóò jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn.

Jóṣúà 20