Jóṣúà 2:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ó sì sọ fún wọn, “Èmi mọ̀ pé Olúwa ti fún un yín ní ilẹ̀ yìí, àti pé ẹ̀rù u yín ti sọ wá di ojo dé ibi pé ìdí gbogbo àwọn tí ó n gbé ilẹ̀ yìí ti di omi nítorí iyín.

10. Àwa ti gbọ́ bí Olúwa ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì; àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Ṣíhónì àti Ógù, àwọn ọba méjèèjì ti Ámórì ti ìlà-oòrùn Jọ́dánì, tí ẹ̀yin parun pátapáta.

11. Bí a ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí; ọkàn an wa pámi, kò sì sí okun kankan fún wa mọ́ nítorí i yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ní ayé.

12. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ búra fún mi ní ti Olúwa pé ẹ̀yin yóò ṣe àánú fún ìdílé mi, nítorí pé mo ti ṣe yín ní oore. Ẹ fún mi ní àmì tó dájú:

13. pé ẹ̀yin yóò dá ẹ̀mí baba àti ìyá mi sí; arákùnrin mi àti arábinrin mi, àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, àti pé ẹ̀yin yóò gbà wá là lọ́wọ́ ikú.”

14. “Ẹ̀mí wa fún ẹ̀mí in yín!” àwọn ọkùnrin náà mú dá a lójú. “Tí ìwọ kò bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò sì fi òtítọ́ àti àánú bá ọ lò nígbà tí Olúwa bá fún wa ní ilẹ̀ náà.”

Jóṣúà 2