4. Ṣùgbọ́n obìnrin náà ti mú àwọn ọkùnrin méjì náà, o sì fi wọ́n pamọ́. Ó sì wí pé, “lóótọ́ ní àwọn ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ibi tí wọ́n ti wá.
5. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, nígbà tí ó tó àkókò làti ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè, àwọn ọkùnrin náà sì jáde lọ. Èmi kò sì mọ ọ̀nà tí wọ́n gbà lọ. Ẹ lépa wọn kíákíá. Ẹ̀yin yóò bá wọn.”
6. (Ṣùgbọ́n ó ti mú wọn gòkè àjà, ó sì fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ pòròpòrò ọkà tó tò jọ sí orí àjà.)
7. Àwọn ọkùnrin náà jáde lọ láti lépa àwọn amí náà ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìwọdò Jọ́dánì, bí àwọn tí ń lépa wọn sì ti jáde, wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè.
8. Kí àwọn ayọ́lẹ̀wò náà tó sùn ní alẹ́, ó gòkè tọ̀ wọ́n lọ lókè àjà.
9. Ó sì sọ fún wọn, “Èmi mọ̀ pé Olúwa ti fún un yín ní ilẹ̀ yìí, àti pé ẹ̀rù u yín ti sọ wá di ojo dé ibi pé ìdí gbogbo àwọn tí ó n gbé ilẹ̀ yìí ti di omi nítorí iyín.
10. Àwa ti gbọ́ bí Olúwa ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì; àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Ṣíhónì àti Ógù, àwọn ọba méjèèjì ti Ámórì ti ìlà-oòrùn Jọ́dánì, tí ẹ̀yin parun pátapáta.
11. Bí a ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí; ọkàn an wa pámi, kò sì sí okun kankan fún wa mọ́ nítorí i yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ní ayé.
12. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ búra fún mi ní ti Olúwa pé ẹ̀yin yóò ṣe àánú fún ìdílé mi, nítorí pé mo ti ṣe yín ní oore. Ẹ fún mi ní àmì tó dájú:
13. pé ẹ̀yin yóò dá ẹ̀mí baba àti ìyá mi sí; arákùnrin mi àti arábinrin mi, àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, àti pé ẹ̀yin yóò gbà wá là lọ́wọ́ ikú.”