Jóṣúà 19:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Gègé kẹrin jáde fún Ísákárì, agbo ilé ní agbo ilé.

18. Lára ilẹ̀ wọn ni èyí:Jésíréélì, Késúlótì, Súnemù,

19. Háfáráímù, Ṣíhónì, Ánáhárátì,

20. Rábítì, Kíṣíónì, Ébésì,

21. Rémétì, Ẹni-Gánnímù, Ẹni-Hádà àti Bẹ́tì-Pásésì.

22. Ààlà náà sì dé Tábórì, Ṣáhásúmà, àti Bẹti Ṣẹ́mẹ́ṣì, ó sì pin ní Jọ́dánì. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rindínlógún àti iletò wọn.

23. Ìlú wọ̀nyí àti iletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Ísákárì, ní agbo ilé agbo ilé.

Jóṣúà 19