1. Gègé kéjì jáde fún ẹ̀yà Símíónì, ní agbo ilé, ní agbo ilé. Ìní wọn sì wà ní àárin ilẹ̀ Júdà.
2. Lára ìpín wọn ní:Béérí Ṣébà (tàbí Ṣẹ́bà), Móládà,
3. Hasari-Ṣúálì, Báláhì, Ésémù,
4. Élítóládì, Bétúlì, Hómà,
5. síkílágì, Bẹti-Mákábótì, Hasari-Súsà,
6. Bẹti-Lébà ati Ṣárúẹ́nì, ìlú wọn jẹ́ mẹ́talá àti ìletò wọn.
7. Háínì, Rímónì, Étérì àti Áṣánì: Ìlú wọn jẹ́ mẹ́rin àti ìletò wọn:
8. Àti gbogbo àwọn agbégbé ìlú wọ̀nyí títí dé Baalati-Béérì (Rámà ní Négéfì).Èyí ni ìní àwọn ọmọ Símíónì, agbo ilé, ní agbo ilé.
9. A mú ogún ìní àwọn ọmọ Símíónì láti ìpín Júdà, nítorí ìpín Júdà pọ̀ ju èyí tí wọ́n nílò lọ. Báyìí ni àwọn ọmọ Símíónì gba ìní wọn ní àárin ilẹ̀ Júdà.