Jóṣúà 11:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. àti sí àwọn ọba ìhà àríwá tí wọ́n wà ní orí òkè ní aginjù, gúsù ti Kínérótù, ní ẹsẹ̀ òkè ìwọ̀-oòrùn àti ní Nafotu Dórì ní ìwọ̀-oòrùn;

3. sí àwọn ará Kénánì ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Ámórì, Hítì, Pérísì àti Jébúsì ní orí òkè; àti sí àwọn Hífì ní ìsàlẹ̀ Hámónì ní agbégbé Mísípà.

4. Wọ́n sì jáde pẹ̀lú gbogbo ogun wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun ńlá, wọ́n sì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun

5. Gbogbo àwọn ọba yìí pa ọmọ ogun wọn pọ̀, wọ́n sì pa ibùdó sí ibi omi Mérómù láti bá Ísírẹ́lì jà.

Jóṣúà 11