15. Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró,yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́
16. Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú òòrùn,ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.
17. Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká,ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.
18. Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀,nígbà náà ni ipò náà sẹ́ ẹ pé, ‘Èmi kò ri ọ rí!’