Jóòbù 8:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ?Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?

11. Koríko odò ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀tàbí èèsú ha lè dàgbà láìlómi?

12. Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò kee lulẹ̀,ó rọ dànù, ewéko mìíràn gbogbo hù dípò rẹ̀

13. Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run,àbá àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.

Jóòbù 8