14. Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da ẹ̀gbọ̀n bò mi,ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rù bà mí.
15. Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti soàti ikú ju kí ń wà láàyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ.
16. O ṣú mi, èmi kò le wà títí:jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi.
17. “Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀?Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọ̀kàn rẹ lé e?
18. Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀,ti ìwọ o sì máa dán anwò nígbàkúgbà!
19. Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ,tí ìwọ o fi jọ títí èmi o fi lè dá itọ́ mi mì.
20. Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó se sí ọ.Ìwọ Olùtọ́jú ènìyàn?Èéṣe tí ìwọ fi mí ṣe àmì ìtasi niwájú rẹ,bẹ́ẹ̀ ni èmi si di erù-wúwo sì ara rẹ̀
21. Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn,kí ìwọ kí ó sì mú aìṣédéédéé mi kúrò?Ǹjẹ́ nísinsìn yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀,ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní owúrọ̀, èmi kì bá tí sí.”