Jóòbù 6:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,tàbí ọ̀dá-màlúù a máa dún sórí ìjẹ rẹ̀?

6. A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,tàbi adùn ha wà nínú fúnfún eyin?

7. Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò,òun ni ó dàbí oúnjẹ mi tí kò ní adùn.

8. “Áà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.

9. Àní Ọlọ́rin ìbá jẹ́ pa mí run,tí òun ì bá jẹ́ siwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.

Jóòbù 6