Jóòbù 41:25-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè,àwọn alágbára bẹ̀rù; nítoríìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.

26. Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbi ọfà, ẹni tí ó sáa kò lè rán an.

27. Ó ká ìrin sí bi koríko gbígbẹ àtiidẹ si bi igi híhù.

28. Ọfà kò lè mú un sá; òkútakànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àkékù koríko.

29. Ó ka ẹṣin sí bí àkékù idi koríko;ó rẹ́rin-ín sí mímì ọ̀kọ̀.

30. Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀, ósì tẹ́ ohun mímú ṣónṣó sórí ẹrẹ̀.

Jóòbù 41