Jóòbù 40:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. “Di àmùrè gíri ní ẹgbẹ́ rẹ, èmi ó biọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

8. “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo

9. Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lèfi ohùn sán àrá bí òun?

10. Fi ọlá ńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ararẹ ní ọ̀ṣọ́, tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bi ara ní aṣọ.

11. Mú ìrúnu ìbínú rẹ jáde; kíyèsígbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀

12. Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyànkí o sì rẹ ẹ sílẹ̀, kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.

13. Sin gbogbo wọn pa pọ̀ nínúerùpẹ̀, kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú

14. Nígbà náà ní èmi ó yàn ọ́ pé,ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.

Jóòbù 40