7. Ó rẹ́rìnín sí ariwo ìlú, bẹ́ẹ̀ niÒun kò sì gbọ́ igbe darandaran.
8. Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjókòó rẹ̀,Òun asì má a wá ewé tútù gbogbo rí.
9. “Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí? Tàbí,ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?
10. Ìwọ le fi òkò tata de àgbáǹrérénínú aporo? Tàbí ó jẹ́ máa faìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?
11. Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀ lée nítorí agbára rẹ̀pọ̀ ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?