Jóòbù 39:22-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kòsì fòó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà ṣẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.

23. Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mìpẹ́kẹ́pẹ́kẹ́, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.

24. Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbéilẹ̀ mì, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbàá gbọ́ pé, ìró ipè ni.

25. Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà!Ó sì gbóhùn ogun lókè réré, araàwọn balógun àti ariwo ogun wọn.

26. “Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fòsókè tí ó sì mọ ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúsù?

Jóòbù 39