21. Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ síagbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.
22. Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kòsì fòó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà ṣẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.
23. Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mìpẹ́kẹ́pẹ́kẹ́, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.
24. Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbéilẹ̀ mì, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbàá gbọ́ pé, ìró ipè ni.
25. Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà!Ó sì gbóhùn ogun lókè réré, araàwọn balógun àti ariwo ogun wọn.
26. “Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fòsókè tí ó sì mọ ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúsù?
27. Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè kí ósì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga?
28. Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta,lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè.
29. Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ́kiri, ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré.
30. Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀,níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”