18. Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó ganẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.
19. “Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí? tàbí ṣéÌwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ?
20. Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà?Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá;
21. Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ síagbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.
22. Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kòsì fòó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà ṣẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.
23. Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mìpẹ́kẹ́pẹ́kẹ́, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.
24. Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbéilẹ̀ mì, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbàá gbọ́ pé, ìró ipè ni.
25. Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà!Ó sì gbóhùn ogun lókè réré, araàwọn balógun àti ariwo ogun wọn.