1. “Ìwọ mọ àkókò ìgbà tíàwọn ewúrẹ́ orí àpáta ìbímọ? Ìwọsì lè kíyèsí ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ?
2. Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pè,ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ,
3. Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bí mọ,wọ́n sì mú ìkáànú wọn jáde.
4. Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́ndàgbà nínú ọ̀dàn; wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn.