23. Tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu,dé ọjọ́ ogun àti ìjà?
24. Ọ̀nà wo ǹi ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ńya, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?
25. Ta ni ó la ipadò fún ẹkun omi, àtiọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
26. Láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tíènìyàn kò sí, ní ihà níbi tí ènìyàn kò sí;