Jóòbù 38:19-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. “Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé? Bí óṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀,

20. Tí ìwọ í fi mú un lọ síbi àlá rẹ̀, tíìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀?

21. Ìwọ mọ èyí, nitorí nígbà náà nia bí ọ? Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀.

22. “Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì Sínóò lọ ríbí, kìwọ sì rí ilé ìṣúrà òjò rí,

23. Tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu,dé ọjọ́ ogun àti ìjà?

24. Ọ̀nà wo ǹi ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ńya, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?

Jóòbù 38