Jóòbù 38:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nígbà tí mo ṣe òpin fún-un, tímo sì se bèbè àti ìlẹ̀kùn,

11. Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé,kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?

12. “Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbàọjọ́ rẹ̀ wá ìwọ sì mú ìlà oòrùn mọ ipò rẹ̀,

13. Kí ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lègbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?

14. Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdìamọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.

Jóòbù 38