Jóòbù 37:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná Òun kan fọ̀ramúramù; ó sì fi ohùn ọláńlárẹ̀ sán àrá; òhun kì yóò sì dáàrá dúró nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.

5. Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá níọ̀nà ìyanu; ohùn ńláńlá ni íṣe tí àwa kò le mọ̀.

6. Nítori tí ó wí fún Sínóó pé, Ìwọ rọ̀sílẹ̀ ayé, àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, àti fún òjò ńlá agbára rẹ̀.

7. Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kígbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀ó sì tún dá olúkúlùkù ẹ̀nìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀

8. Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inúihò lọ, wọn a sì wà ni ipò wọn.

9. Láti ìhà gúsù ni ìjì àjàyíká tí jádewá, àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọ̀sánmọ̀ ká.

10. Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fí ìdí-omi fúnni, ibú-omi á sì sún kì.

Jóòbù 37