Jóòbù 35:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Elíhù sì wí pe:

2. “Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé,òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?

3. Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóòjá sí fún ọ, tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.

4. “Èmi ó dá ọ lóhùn àti àwọn ẹgbẹ́ rẹpẹ̀lú rẹ.

5. Ṣíjú wo ọ̀run; kí o rí i, ki o sìbojúwo àwọ̀sánmọ̀ tí ó ga jù ọ lọ

Jóòbù 35