Jóòbù 34:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Élíhù dáhùn, ó sì wí pé:

2. “Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye.

3. Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò,bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò.

4. Ẹ jẹ́ kí a ṣà ẹ̀tọ́ yàn fún ara wa;ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrin wa.

5. “Nítorí pé Jóòbù wí pé, ‘Aláìlẹ́sẹ̀ ni èmi;Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ.

6. Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí,bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò níàwòtán dídì ọgbẹ́.’

7. Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jóòbù,tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?

8. Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ósì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.

9. Nítorí ó sá ti wí pé,‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn,tí yóò fí máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’

10. “Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetí sílẹ̀ sí miẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye:Ódodi fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú àti fúnOlódùmárè, tí yóò fí ṣe àìṣedéédéé!

11. Nítorí pé ó ń sá fún ènìyàn fúnohun tí a bá ṣe, yóò sì múolúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀.

12. Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkúwà;bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po.

13. Ta ni ó yàn ań lórí, tàbí ta ni ófi gbogbo ayé lée lọ́wọ́?

14. Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀tí ó sì gba ọkàn rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,

15. gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀,ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀.

16. “Ǹjẹ́ nisinsìnyí, bí ìwọ bá ní òye, gbọ́ èyí;fetísí ohùn ẹnu mi.

17. Ẹni tí ó kóríra òtítọ́ ha le iṣe olóríbí? Ìwọ ó hà sì dá olóótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?

Jóòbù 34