Jóòbù 33:28-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. ó ti gba ọkàn mi kúrò nínú ìlọsínú ihò, ẹ̀mí mi yóò sì rí ìmọ́lẹ̀!

29. “Wò ó! Nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́runmáa ń ṣe fún ènìyàn nígbà méjì àti nígbà mẹ́ta,

30. Láti mú ọkàn rẹ padà kúrò nínúisà òkú, láti fi ìmọ́lẹ̀ alààyè mọ́ sí i.

31. “Jóòbù, kíyèsìí gidigidi kí o sì fetísí mi; pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì máa sọ ọ́

32. Bí ìwọ bá sì ní ohun íwí, dámi lóhùn; máa sọ, nítorí pé èmi fẹ́ dá ọ láre.

33. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbọ́ tèmi; pa ẹnu rẹmọ́ èmi ó sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n.”

Jóòbù 33