23. “Bí oníṣẹ́ kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tíń ṣe alágbàwí, ọ̀kan ninú ẹgbẹ̀rún láti fi ọ̀nà pípé hàn ni,
24. Nígbà náà ni ó ṣe oore ọ̀fẹ́ fún un ó sìwí pé, gbà á kúrò nínú ìlọ sínúìsà òkú èmi ti ràá pàdà;
25. Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọkékeré, yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀;
26. Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì seoju rere rẹ̀, o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lúayọ̀, òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn
27. Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé èmiṣẹ̀, kò sì sí èyí tí o tọ́, mo sì tiyí èyí tí ó tọ́ po, a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi;