2. Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sími,níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?
3. Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyànwọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹní ibi ìkọsílẹ̀ ní òru.
4. Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀báìgbẹ́; gbogbo igikígi ni ounjẹ jíjẹ wọn.
5. A lé wọn kúrò láàrin ènìyàn,àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.
6. A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkùtaàfonífojì, nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.
7. Wọ́n ń dún bí ẹranko ní àárinìgbẹ́, wọ́n kó ara wọn jọpọ̀ ní abẹ́ èṣìsì.
8. Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé, àníàwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀.
9. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ńfi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin; àníèmi di ẹni ìsọ̀rọ̀ sí láàrin wọn.